Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe idupẹ ẹrú fun Olúwa rẹ lórí ọla Rẹ ati awọn idẹra Rẹ wa ninu awọn alamọri ti maa n fa iyọnu Ọlọh...
Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da...
Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si...
Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sin, o maa n: Akọkọ: O maa gbe ọwọ rẹ, tabi aṣọ rẹ sori ẹnu rẹ; ki nnkan kan ma baa jade lati ẹnu r...
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Ọlọhun ba fẹ oore fun ọkan ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ mumini, o maa fi àdánwò kan wọn ninu ẹmi wọ...

Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”

Lati ọdọ Salamah ọmọ Al-hakwa'u- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa", nnkan ko kọdi rẹ afi igberaga, o sọ pe: Ko si lee gbe e si ẹnu rẹ mọ.

Lati ọdọ Abu Hurayra– ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba sin, o maa n gbe ọwọ rẹ- tabi aṣọ rẹ- si ẹnu rẹ, ti o maa fi rẹ ohun rẹ nilẹ.

Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju Ọlọhun maa n fẹ́ lati mu awọn ofin idẹkun Rẹ wa, gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ lati mu awọn eyi ti o jẹ dandan wa”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”.

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy ati lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".

Lati ọdọ Suhayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini, ti idunu ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ, ti yio si jẹ oore fun un, ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru, ti yio si tun jẹ oore fun un».

Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia".

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de, ti ọmọniyan o ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, ti yio ta ẹsin rẹ tori adun aye ti ko nii pẹ tan.

Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin, olùpín ni mi, Ọlọhun ni n fúnni, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti àṣẹ Ọlọhun yoo fi dé”.

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn, ẹ si ma ṣẹsa lati wa ni iwájú ni àwọn àpéjọ pẹ̀lú ẹ, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn, iná ni, iná ni”.

Lati ọdọ Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn”.