- Ijẹ dandan didirọ mọ ẹsin, ati yiyara sibi iṣẹ oloore siwaju ki awọn adinilọwọ o to kọdi.
- Itọka si itẹlera awọn fitina ti maa n sọni nu ni igbẹyin aye, ati pe bi fitina kan ba ṣe n lọ ni omiran o maa rọpo rẹ.
- Ti ẹsin ọmọniyan ba ti lẹ ti o si fi ẹsin silẹ latari awọn alamọri aye gẹgẹbi owo tabi nkan miran, iyẹn o jẹ okunfa yiyẹgẹrẹ rẹ ati gbigbe ẹsin rẹ jusilẹ ati sisa tẹle awọn fitina yẹn.
- O wa ninu hadīth yii itọka si pe dajudaju awọn iṣẹ oloore okunfa ọla ni wọ́n jẹ nibi awọn fitina.
- Awọn fitina ipin meji ni: Awọn fitina awọn iruju, iwosan rẹ ni imọ, awọn fitina awọn adun, iwosan rẹ ni igbagbọ ati suuru.
- O wa ninu hadīth yii itọka lórí pe dajudaju ẹni ti iṣẹ rẹ ba kere fitina o yara de ọdọ rẹ, ati pe ẹni ti iṣẹ rẹ ba pọ ki o ma gba ẹtan pẹlu nkan ti n bẹ lọdọ rẹ bi ko ṣe pe ki o tun wa alekun.