Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, ni arákùnrin kan ba yọ si wa, ti aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dúdú gan, a ko ri oripa ìrìn-àjò ni ara rẹ, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó si ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fi eékún rẹ méjèèjì tì sí ara eékún rẹ méjèèjì, o wa gbe ọwọ́ rẹ méjèèjì lori itan rẹ, o wa sọ pé: Irẹ Muhammad, sọ fún mi nipa Islam, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ”, o sọ pé: Òdodo ni o sọ, o sọ pé: Ẹnu yà wá fun un, o n bi i leere, o si tun n sọ pé òdodo ni o sọ, o sọ pé: Sọ fun mi nipa igbagbọ, o sọ pé: “Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ̀, ati awọn ìwé Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o si ni igbagbọ ninu kádàrá, oore rẹ ni ati aburu rẹ”, o sọ pe: Òdodo ni o sọ, o sọ pe: Sọ fun mi nipa ṣíṣe dáadáa, o sọ pe: “Ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ìwọ ko ba ri I, Òun n ri ọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa àsìkò ti aye maa parẹ, o sọ pe: “Ẹni ti wọn n beere nipa nǹkan lọ́wọ́ rẹ ko ni imọ nipa nǹkan naa ju ẹni tí n beere lọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa awọn àmì rẹ, o sọ pe: “Ki ẹrú lóbìnrin bi olówó rẹ, ati ki o ri awọn ti ko wọ bàtà ti wọn wa ni ihoho ti wọn jẹ tálákà tí wọn n da ẹran jẹ, ti wọn yoo maa fi ile gíga ṣe iyanran”, o sọ pe: Lẹ́yìn naa o pẹyin da, mo wa wa nibẹ fun ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà ni o wa sọ fún mi pe: “Irẹ Umar, ǹjẹ́ o mọ onibeere naa?”, mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Jibril ni, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin”.