- Adura ṣíṣe jẹ ijọsin wọn ko gbọdọ yi i afi sọ́dọ̀ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Ọla ti o n bẹ fun imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ku lori rẹ maa wọ alujanna, kódà ki wọn fi iya jẹ ẹ lori awọn ẹṣẹ rẹ kan.
- Aburu ti o n bẹ fun ẹbọ, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ku lori rẹ maa wọ ina.