The Encyclopedia of Ar-Rahman's Guests

Selected material for Pilgrims and Um-rah teaching it in languages of the world

Selected content

Àlékún

Selected Quranic verses

{Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.[1] (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.} (Suuratu Al-Imran : 96).
إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn[1] ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.} (Suuratul Maaidah : 1).
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَوۡفُواْ بِٱلۡعُقُودِۚ أُحِلَّتۡ لَكُم بَهِيمَةُ ٱلۡأَنۡعَٰمِ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ غَيۡرَ مُحِلِّي ٱلصَّيۡدِ وَأَنتُمۡ حُرُمٌۗ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ مَا يُرِيدُ
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe rú òfin àwọn n̄ǹkan àríṣàmì tí Allāhu gbékalẹ̀ fún ẹ̀sìn Rẹ̀ (nínú iṣẹ́ hajj). Ẹ má ṣe rú òfin oṣù ọ̀wọ̀, àti ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ẹ má ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti lọ sí Ilé Haram, tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Tí ẹ bá sì ti túra sílẹ̀ nínú aṣọ hurumi, nígbà náà ẹ (lè) dọdẹ (ẹranko). Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkórira àwọn ènìyàn kan tì yín láti tayọ ẹnu-ààlà nítorí pé, wọ́n ṣe yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ ran ara yín lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ má ṣe ran ara yín lọ́wọ́ lórí (ìwà) ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtayọ ẹnu-ààlà. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.} (Suuratul Maaidah : 2).
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُحِلُّواْ شَعَٰٓئِرَ ٱللَّهِ وَلَا ٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَلَا ٱلۡهَدۡيَ وَلَا ٱلۡقَلَٰٓئِدَ وَلَآ ءَآمِّينَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّهِمۡ وَرِضۡوَٰنٗاۚ وَإِذَا حَلَلۡتُمۡ فَٱصۡطَادُواْۚ وَلَا يَجۡرِمَنَّكُمۡ شَنَـَٔانُ قَوۡمٍ أَن صَدُّوكُمۡ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ أَن تَعۡتَدُواْۘ وَتَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡبِرِّ وَٱلتَّقۡوَىٰۖ وَلَا تَعَاوَنُواْ عَلَى ٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ إِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
{Allāhu ṣe Kaabah Ilé Ọ̀wọ̀ ní ibùdúró ṣẹ̀sìn fún àwọn ènìyàn. (N̄ǹkan ààbò náà ni) àwọn oṣù ọ̀wọ̀, àwọn ẹran ọrẹ (tí wọn kò ṣàmì sí lọ́rùn) àti (àwọn ẹran ọrẹ) tí wọ́n ṣàmì sí lọ́rùn. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí kí ẹ lè mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.} (Suuratul Maaidah : 97).
۞ جَعَلَ ٱللَّهُ ٱلۡكَعۡبَةَ ٱلۡبَيۡتَ ٱلۡحَرَامَ قِيَٰمٗا لِّلنَّاسِ وَٱلشَّهۡرَ ٱلۡحَرَامَ وَٱلۡهَدۡيَ وَٱلۡقَلَٰٓئِدَۚ ذَٰلِكَ لِتَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَأَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٌ
{Lẹ́yìn náà, kí wọ́n yanjú ìdọ̀tí ara wọn fún ìparí iṣẹ́ Hajj wọn, kí wọ́n mú àwọn ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, kí wọ́n sì yípo Ilé Láéláé náà.} (Suuratul Hajj : 29).
ثُمَّ لۡيَقۡضُواْ تَفَثَهُمۡ وَلۡيُوفُواْ نُذُورَهُمۡ وَلۡيَطَّوَّفُواْ بِٱلۡبَيۡتِ ٱلۡعَتِيقِ

Selected prophetic hadiths

Lati ọdọ ọmọ umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní oun gbọ lẹnu ọkunrin kan ti n sọ pe: Rara o, oun fi Kaabah búra, ọmọ umar wa sọ fun un pe: A...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo pé ẹnikẹni tí ó bá fi nkan miran búra yatọ si Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ọlọhun sọ pe: Maa na owó irẹ ọmọ Anọbi Adam,...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Ọlọhun sọ pe: Irẹ ọmọ Adam, maa ná owó- ninu awọn ìnáwó ti o jẹ dandan ati eyi ti a fẹ́- maa gbòòrò...
Láti ọ̀dọ̀ An-Nuhmaan ọmọ Basheer- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Adua naa ni ìjọsìn”, lẹ...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé adua naa ni ìjọsìn, ohun ti o jẹ dandan naa ni ki gbogbo ẹ jẹ ti Ọlọhun nìkan, yálà o jẹ adua ibeere a...
Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe: “Ìwọ Ọlọhun,...
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tób...
Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe: “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, ko...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ...

Fatwas on Hajj and Umrah

Supplications from the Qur’an and Sunnah