Alukuraani

Share

{Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́[1] Onímọ̀.} (Suuratul Baqarah : 158).
۞ إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِۖ فَمَنۡ حَجَّ ٱلۡبَيۡتَ أَوِ ٱعۡتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِ أَن يَطَّوَّفَ بِهِمَاۚ وَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ
{Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu. Tí wọ́n bá sì se yín mọ́ ojú ọ̀nà, ẹ fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ fá irun orí yín títí di ìgbà tí ẹran ọrẹ náà yó fi dé àyè rẹ̀. Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí ìnira kan ń bẹ ní orí rẹ̀, ó máa fi ààwẹ̀ tàbí sàráà tàbí ẹran pípa ṣe ìtánràn (fún kíkánjú fá irun orí). Nígbà tí ẹ bá fọkànbalẹ̀ (nínú ewu), ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá tó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.} (Suuratul Baqarah : 196).
وَأَتِمُّواْ ٱلۡحَجَّ وَٱلۡعُمۡرَةَ لِلَّهِۚ فَإِنۡ أُحۡصِرۡتُمۡ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۖ وَلَا تَحۡلِقُواْ رُءُوسَكُمۡ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡهَدۡيُ مَحِلَّهُۥۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ بِهِۦٓ أَذٗى مِّن رَّأۡسِهِۦ فَفِدۡيَةٞ مِّن صِيَامٍ أَوۡ صَدَقَةٍ أَوۡ نُسُكٖۚ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَمَن تَمَتَّعَ بِٱلۡعُمۡرَةِ إِلَى ٱلۡحَجِّ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۚ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖ فِي ٱلۡحَجِّ وَسَبۡعَةٍ إِذَا رَجَعۡتُمۡۗ تِلۡكَ عَشَرَةٞ كَامِلَةٞۗ ذَٰلِكَ لِمَن لَّمۡ يَكُنۡ أَهۡلُهُۥ حَاضِرِي ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ
{Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí wọ́n ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, rírú òfin àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò tó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè.} (Suuratul Baqarah : 197).
ٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ
{Kò sí ìbáwí fún yín (níbi òwò ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ hajj) pé kí ẹ wá oore kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ń darí bọ̀ láti ‘Arafah, ẹ ṣe ìrántí Allāhu ní àyè alápọ̀n-ọ́nlé (Muzdalifah). Ẹ ṣe ìrántí Rẹ̀ nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ wà nínú àwọn olùṣìnà.} (Suuratul Baqarah : 198).
لَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَبۡتَغُواْ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكُمۡۚ فَإِذَآ أَفَضۡتُم مِّنۡ عَرَفَٰتٖ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ عِندَ ٱلۡمَشۡعَرِ ٱلۡحَرَامِۖ وَٱذۡكُرُوهُ كَمَا هَدَىٰكُمۡ وَإِن كُنتُم مِّن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلضَّآلِّينَ
{Lẹ́yìn náà, ẹ dà kúrò láti ibi tí àwọn ènìyàn ti dà kúrò (ìyẹn ní ‘Arafah), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn Allāhu. Dájúdájú, Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.} (Suuratul Baqarah : 199).
ثُمَّ أَفِيضُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَفَاضَ ٱلنَّاسُ وَٱسۡتَغۡفِرُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ
{Nígbà tí ẹ bá parí ìjọ́sìn (Hajj) yín, ẹ ṣèrántí Allāhu gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń ṣèrántí àwọn baba ńlá yín. Tàbí kí ìrántí náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ayé.” Kò sì níí sí ìpín oore kan fún un ní ọ̀run.} (Suuratul Baqarah : 200).
فَإِذَا قَضَيۡتُم مَّنَٰسِكَكُمۡ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَذِكۡرِكُمۡ ءَابَآءَكُمۡ أَوۡ أَشَدَّ ذِكۡرٗاۗ فَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا وَمَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖ
{Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tó ń sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”} (Suuratul Baqarah : 201).
وَمِنۡهُم مَّن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ حَسَنَةٗ وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ
{Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni ìpín oore nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.} (Suuratul Baqarah : 202).
أُوْلَٰٓئِكَ لَهُمۡ نَصِيبٞ مِّمَّا كَسَبُواْۚ وَٱللَّهُ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ
{Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ tó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.[1]} (Suuratul Baqarah : 203).
۞ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ فِيٓ أَيَّامٖ مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن تَعَجَّلَ فِي يَوۡمَيۡنِ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِ وَمَن تَأَخَّرَ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۖ لِمَنِ ٱتَّقَىٰۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ
{Dájúdájú ilé àkọ́kọ́ tí A fi lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn ni èyí tí ó wà ní Bakkah.[1] (Ó jẹ́ ilé) ìbùkún àti ìmọ̀nà fún gbogbo ẹ̀dá.} (Suuratu Al-Imran : 96).
إِنَّ أَوَّلَ بَيۡتٖ وُضِعَ لِلنَّاسِ لَلَّذِي بِبَكَّةَ مُبَارَكٗا وَهُدٗى لِّلۡعَٰلَمِينَ
{Àwọn àmì tó yanjú wà nínú rẹ̀; ibùdúró (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú rẹ̀ ti di ẹni ìfàyàbalẹ̀. Allāhu ṣe àbẹ̀wò sí Ilé náà ní dandan fún àwọn ènìyàn, tó lágbára ọ̀nà tí ó máa gbà débẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀ tí kò bùkátà sí gbogbo ẹ̀dá.} (Suuratu Al-Imran : 97).
فِيهِ ءَايَٰتُۢ بَيِّنَٰتٞ مَّقَامُ إِبۡرَٰهِيمَۖ وَمَن دَخَلَهُۥ كَانَ ءَامِنٗاۗ وَلِلَّهِ عَلَى ٱلنَّاسِ حِجُّ ٱلۡبَيۡتِ مَنِ ٱسۡتَطَاعَ إِلَيۡهِ سَبِيلٗاۚ وَمَن كَفَرَ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ عَنِ ٱلۡعَٰلَمِينَ
{Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn[1] ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́.} (Suuratul Maaidah : 1).
يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَوۡفُواْ بِٱلۡعُقُودِۚ أُحِلَّتۡ لَكُم بَهِيمَةُ ٱلۡأَنۡعَٰمِ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ غَيۡرَ مُحِلِّي ٱلصَّيۡدِ وَأَنتُمۡ حُرُمٌۗ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ مَا يُرِيدُ