- Irẹlẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi fifi Mu’aadh sẹyin rẹ lori nnkan ọ̀gùn rẹ.
- Ọ̀nà ikọnilẹkọọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, nigba ti o paara ipe rẹ fun Mu’aadh lati lè jẹ ki o maa fi ọkàn ba nnkan ti o fẹ sọ lọ.
- Ninu majẹmu jijẹrii pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni ni ki ẹni ti o sọ ọ jẹ olododo ti o ni amọdaju ti ko jẹ onirọ tabi oniyemeji.
- Àwọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ko nii ṣe gbere ninu ina jahannamọ, ti wọn bá wọ̀ ọ́ torí awọn ẹṣẹ wọn; wọn maa mu wọn jade lẹyin ti wọn ba mọ.
- Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun ẹni ti o ba sọ ọ lododo.
- Jijẹ ẹtọ gbigbe sísọ hadiisi ju silẹ ni awọn iṣesi kan ti ibajẹ ba lè ti ara rẹ jẹ yọ.