Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ...
Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ, ó wa sọ pe: Eyi ti o tobi julọ ninu wọn ni ẹbọ ńlá, oun...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: È...
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo ìjọ òun ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀! Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa sọ...
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọ...
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo...
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe Musulumi ko nii jẹ ẹni tí igbagbọ rẹ pe titi ti yoo fi ti ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ" mo sọ pe: Dajudaju ìyẹn tobi, mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o pa ọmọ rẹ; ti o n bẹru ki o maa jẹun pẹlu rẹ" mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣìná".

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni o maa kọ̀? O sọ pe: “Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ mi yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá yapa àṣẹ mi ti kọ̀”.

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".

Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ”.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ fi mi sílẹ̀ lópin ìgbà tí mo ba fi yin sílẹ̀, dajudaju nnkan ti o pa awọn ti wọn ṣáájú yin run ni ibeere wọn ati iyapa wọn si awọn anabi wọn, ti mo ba kọ nnkan kan fun yin ẹ jinna si i, ti mo ba pa yin láṣẹ àlámọ̀rí kan ẹ mu u wa de ibi ti ikapa yin ba mọ".

Lati ọdọ Abdullah ọmọ ‘Amr - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná".

Lati ọdọ Al-Miqdam Bin Ma’dikarib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ".

Lati ọdọ ‘Aaisha ati Abdullahi ọmọ’Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- wọn sọ pé: Nigba ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pọka iku, o bẹ̀rẹ̀ si nii fi aṣọ nu oju rẹ, ti o ba ti wa di pe ko le mí mọ́ daadaa, o maa ka a kuro loju rẹ, o wa sọ bi o ṣe wa bẹẹ pe: “Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi” ti o n ṣe ikilọ kuro nibi nnkan ti wọn ṣe.

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a: “Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".