- Ṣíṣe kikọ awọn mọsalasi lori awọn saare leewọ, tabi kiki irun nibẹ, tabi sisin awọn oku si awọn mọsalasi; lati dina mọ okunfa ẹbọ ṣíṣe.
- Kikọ awọn mọsalasi lori awọn saare, ati gbigbe awọn aworan síbẹ̀, jẹ iṣẹ Juu ati Nasara, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe èyí, dajudaju o ti fi iwa jọ wọn.
- Ṣíṣe yiya aworan awọn nnkan ti wọn ni ẹmi leewọ.
- Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lori saare ti o si ya awọn aworan síbẹ̀, o ti wa ninu ẹni ti o buru julọ ninu ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Idaabo bo Sharia fun agbegbe imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo jẹ idaabo bo kan ti o pe, pẹlu kikọdi gbogbo ọna ti o le ja si ẹbọ ṣiṣe.
- Kikọ kuro nibi aṣẹju nipa awọn ẹni rere; nitori pe o jẹ okunfa kiko sinu ẹbọ ṣíṣe.