- Dandan ni níní ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati titi i ṣáájú ìfẹ́ gbogbo ẹ̀dá.
- Lara ami pípé ìfẹ́ ni: Ríran sunna ojiṣẹ Ọlọhun lọ́wọ́, ati níná ẹ̀mí ati dúkìá tori rẹ.
- Ifẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n beere fun itẹle e nibi àṣẹ ti o ba pa, ati gbigba a ni olódodo nibi ohun ti o ba sọ, ati jíjìnnà si ohun ti o ba kọ̀, ati itẹle e, ati fifi adadaalẹ sílẹ̀.
- Ẹ̀tọ́ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tobi o si kanpá ju ti gbogbo èèyàn lọ; torí pé o jẹ okùnfà imọna wa kúrò nibi anù, ati yíyọ wa kuro nibi iná, ati wiwọ alujanna.