Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun t...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèr...
Lati ọdọ 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu ẹsin tabi ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ẹri kankan ko da le e...
Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan,...
Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe Jibril wa ba àwọn saabe ni àwòrán arákùnrin kan ti wọn kò mọ̀. Lára àwọn ìròyìn rẹ ni pe àwọn aṣọ r...
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi Isilaamu jọ ile kan ti wọn mọ daadaa pẹlu origun maarun ti o gbe ile naa duro, ti awọn iwa Isilaamu ti o s...
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ p...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin, ati iwọ awọn ẹrusin lori Ọlọhun, ati pe iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni...

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ohun ti ọmọniyan ba gba lero ni yoo maa jẹ tiẹ̀, ẹni tí hijra tiẹ̀ ba jẹ tori ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, hijra rẹ maa jẹ ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ẹni tí hijra rẹ ba jẹ torí ayé ti o fẹ ki ọwọ rẹ o tẹ̀ tabi torí obìnrin ti o fẹ́ fẹ́, hijra rẹ maa jẹ ohun ti o ba tori rẹ ṣe hijra ni”. Ninu gbólóhùn kan ti o jẹ ti Bukhaariy: “Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero”.

Lati ọdọ 'Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, wọn maa da a pada ni" Bukhari ati Muslim ni wọn gba a wa. O n bẹ fun Muslim pé: "Ẹni ti o ba ṣe iṣẹ kan ti ko si àṣẹ wa nibẹ, wọn maa da a pada ni"

Láti ọ̀dọ̀ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Láàrin ìgbà tí a wa ni ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, ni arákùnrin kan ba yọ si wa, ti aṣọ rẹ funfun gan, ti irun rẹ naa si dúdú gan, a ko ri oripa ìrìn-àjò ni ara rẹ, ẹni kankan ko si mọ ọn ninu wa, titi ti o fi jókòó si ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fi eékún rẹ méjèèjì tì sí ara eékún rẹ méjèèjì, o wa gbe ọwọ́ rẹ méjèèjì lori itan rẹ, o wa sọ pé: Irẹ Muhammad, sọ fún mi nipa Islam, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ”, o sọ pé: Òdodo ni o sọ, o sọ pé: Ẹnu yà wá fun un, o n bi i leere, o si tun n sọ pé òdodo ni o sọ, o sọ pé: Sọ fun mi nipa igbagbọ, o sọ pé: “Ki o ni igbagbọ ninu Ọlọhun, ati awọn malaika Rẹ̀, ati awọn ìwé Rẹ, ati awọn ojiṣẹ Rẹ, ati ọjọ́ ìkẹyìn, ki o si ni igbagbọ ninu kádàrá, oore rẹ ni ati aburu rẹ”, o sọ pe: Òdodo ni o sọ, o sọ pe: Sọ fun mi nipa ṣíṣe dáadáa, o sọ pe: “Ki o maa jọ́sìn fun Ọlọhun bii pe o n ri I, ti ìwọ ko ba ri I, Òun n ri ọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa àsìkò ti aye maa parẹ, o sọ pe: “Ẹni ti wọn n beere nipa nǹkan lọ́wọ́ rẹ ko ni imọ nipa nǹkan naa ju ẹni tí n beere lọ”, o sọ pe: Sọ fún mi nipa awọn àmì rẹ, o sọ pe: “Ki ẹrú lóbìnrin bi olówó rẹ, ati ki o ri awọn ti ko wọ bàtà ti wọn wa ni ihoho ti wọn jẹ tálákà tí wọn n da ẹran jẹ, ti wọn yoo maa fi ile gíga ṣe iyanran”, o sọ pe: Lẹ́yìn naa o pẹyin da, mo wa wa nibẹ fun ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà ni o wa sọ fún mi pe: “Irẹ Umar, ǹjẹ́ o mọ onibeere naa?”, mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Jibril ni, o wa ba yin lati kọ yin ni ẹsin yin”.

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».

Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe: Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: “Irẹ Mu’aadh”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: “Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: “Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.

Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.

Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.

Lati ọdọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ fun Muaz ọmọ Jabal, nigba ti ó ran an lọ sí ilu Yemen pé: "Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé dajudaju Ọlọhun ti ṣe irun wakati márùn-ún ní ọranyan lé wọn lori ni ojoojumọ, tí wọ́n bá gba e gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé Ọlọ́hun ti ṣe zakat ní ọranyan lé wọn lori, kí wọ́n maa gbà a lọ́wọ́ àwọn olówó inu wọn, kí wọ́n sì maa fún awọn talaka inu wọn, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, ó wá dọwọ́ ẹ o nibi awọn nkan tó niye lori ninu awọn dukia wọn, kí o sì bẹ̀rù ipepe eni tí a ṣe àbòsí sí, nítorí pé kò sí gaga kankan láàrín rẹ̀ àti Ọlọ́hun".

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé: Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.