- Igbagbọ jẹ awọn ipo ti awọn kan lọla ju awọn kan lọ.
- Igbagbọ jẹ ọrọ ati iṣẹ ati adisọkan.
- Itiju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa n beere fun: Ki Ó má ri ẹ níbi tí O kọ fun ẹ, ki O si ma wá ẹ tì nibi ti O pa ẹ láṣẹ.
- Didarukọ onka ko túmọ̀ si pe orí rẹ̀ ni ó ti mọ, bi ko ṣe pe o n da lori pipọ awọn iṣẹ igbagbọ, nitori pe Larubawa le darukọ onka fun nnkan ti ko si nii gbero kikọ nnkan ti o yatọ si i.