Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé: "Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn irant...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé iranti Ọlọhun tó lọ́lá jùlọ ni: "LAA ILAAHA ILLALLOOH" itumọ rẹ̀ ni pé kò sí nkankan tí a gbọd...
Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọkalẹ si...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ ìjọ rẹ sọ́nà lọ sibi ìdìrọ̀mọ́ ati ìsádi ti o maa ṣe àǹfààní ti gbogbo nnkan ti a n ṣọ́ra fun ti èèyàn...
Lati ọdọ Abu Humayd tabi lati ọdọ Abu Usayd, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi k...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – tọka awọn ijọ rẹ sibi adua ti wọn maa ṣe nigba ti wọn ba fẹ wọ masalaasi: (Allāhummo iftah li abwaaba rahmoti...
Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé: "Ti ọkùnrin ba wọ inu i...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pàṣẹ pẹlu riranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati ṣíwájú jijẹ oúnjẹ, ti o ba ranti Ọlọhun pẹlu sisọ pe: (Bismi...

Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí n sọ pé: "Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH".

Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”.

Lati ọdọ Abu Humayd tabi lati ọdọ Abu Usayd, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba fẹ wọ masalaasi ki o yaa sọ pe: Allāhummo iftah li abwaaba rahmotika, ti o ba si tun jade ki o sọ pe: Allāhummo inni as’aluka min fadlika».

Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pe o gbọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pé: "Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa, ti o ba wa wọle, ti ko ṣe iranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ẹ ti ri ibùsùn, ti ko ba ti dárúkọ Ọlọhun nibi oúnjẹ rẹ, o maa sọ pe: Ẹ ti ri ibusun ati oúnjẹ alẹ".