- Ṣíṣe iranti Ọlọhun nigba wiwọ inu ile ati oúnjẹ ni nnkan ti a fẹ, nitori pe Shaitan maa n gbe inu awọn ile, ti o si maa n jẹ oúnjẹ awọn ara ile ti wọn ko ba dárúkọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Shaitan maa n ṣọ ọmọ Adam nibi iṣẹ rẹ ati ìwà rẹ ati nibi awọn àlámọ̀rí rẹ pata, ti o ba gbagbe lati ranti Ọlọhun, ọwọ rẹ maa tẹ erongba rẹ lọdọ rẹ.
- Iranti maa n le Shaitan dànù.
- Gbogbo èṣù kọọkan lo ni awọn ọmọlẹyin rẹ ati awọn ààyò rẹ ti wọn maa n dunnu pẹlu ọrọ rẹ ti wọn si n tẹle àṣẹ rẹ.