- A fẹ ki a ṣe adua yii nigba ti a ba fẹ wọ masalaasi ati nigba ti a ba fẹ jade kuro nibẹ.
- Sisẹsa didarukọ ikẹ nigba ti a ba fẹ wọle, ati ọla nigba ti a ba fẹ jade: Dajudaju ẹni ti o n wọle ko airoju pẹlu nkan ti yio sun un mọ Ọlọhun ati alujanna, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ikẹ, ati pe nigba ti o ba jade yio kaakiri ori ilẹ lati wa ọla Ọlọhun ninu jijẹ-mimu lọ, nitori naa o ṣe deedee ki o darukọ ọla.
- Awọn asikiri yii a maa n sọ wọn nigba ti a ba gbero lati wọ masalaasi, ati nigba ti a ba gbero lati jade kúrò nibẹ.