Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, t...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣeni lojukokoro lati maa da ẹbí pọ pẹ̀lú abẹwo ati apọnle ti ara ati ti owó, ati nǹkan ti o yatọ si i, oun...
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o gba a wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - ó sọ pé: "Kii ṣe ẹniti n fi dáa...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé dajudaju eniyan tó pé nibi siso okun-ẹbi ati ṣiṣe daadaa si awọn ibatan rẹ̀ kii ṣe eniyan tí...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ p...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pàápàá ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn ti o jẹ eewọ, oun naa ni: Sísọ nipa Mùsùlùmí ti ko si ni tòsí ohun ti o maa kori...
Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hu...
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe alaye pe dajudaju gbogbo nkan ti o ba ti le mu laakaye lọ ni ọti ti n pa eeyan, yala o jẹ mímu tabi jijẹ ta...
Lati ọdọ Abu Huraira, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ ibi ilejina si ikẹ Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn le ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a. Ati pe n...

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o gba a wa lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - ó sọ pé: "Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà".

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira”, wọn sọ pé: Ti ohun ti mo n sọ ba n bẹ lara ọmọ-ìyá mi ńkọ́? O sọ pe: “Ti ohun ti o n sọ ba n bẹ lara ọmọ-iya rẹ, o ti sọ ọrọ rẹ lẹ́yìn nìyẹn, ṣùgbọ́n ti ko ba si lara rẹ, o ti dá àdápa irọ́ mọ ọn nìyẹn”.

Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin».

Lati ọdọ Abu Huraira, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ).

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ, ẹ ma ṣe maa ọ̀nà láti tu ihoho ara yin sita, ki ẹ si ma maa tọpinpin ara yin, ki ẹ si ma maa ṣe keeta ara yín, ki ẹ si ma maa kọ ẹyin si ara yin, ki ẹ si ma maa korira ara yín, ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya".

Láti ọ̀dọ̀ Huzaefah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Olófòfóó ko nii wọ alujanna”.

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».

Lati ọdọ ọmọ ‘Umar – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ba awọn eeyan sọrọ ni ọjọ ti wọn ṣi Makkah, ni o wa sọ pe: «Mo pe ẹyin eeyan, dajudaju Ọlọhun ti gbe kuro fun yin igberaga igba aimọkan ati ṣiṣe iyanran wọn pẹlu awọn baba wọn, nitori naa meji ni awọn eeyan: eniire olupaya alapọn-ọnle lọdọ Ọlọhun, ati onibajẹ oloriibu ẹni yẹpẹrẹ lọdọ Ọlọhun, awọn eeyan, ọmọ Anabi Aadam ni wọn, ti Ọlọhun si da Aadam lati ibi erupẹ, Ọlọhun sọ pe: {Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni t’ó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán} [Al-Hujrāt: 13]».

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Bakrah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni”, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a gbọ ti ẹni tí o pa èèyàn, ẹni tí wọ́n pa wa nkọ? O sọ pé: “Oun naa fẹ́ pa ẹni keji rẹ ni”.

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: «Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa».