- Aidaa mimaa fi ẹṣẹ han lẹyin ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti bo aṣiri rẹ.
- O n bẹ nibi imaa fi ẹṣẹ han titan ibajẹ ka laarin awọn Mumuni.
- Ẹni ti Ọlọhun ba bo ni àṣírí ní aye yio bo o ni aṣiri ni ọjọ ikẹyin, ati pe eleyii wa ninu gbigbaaye ikẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu awọn ẹru Rẹ.
- Ẹni ti wọn ba fi ẹṣẹ ṣe adanwo fun ki o bo ara rẹ ni àṣírí ki o si tuba lọ si ọdọ Ọlọhun.
- Titobi ẹṣẹ awọn alaṣehan awọn ti wọn mọọmọ maa n fi ẹṣẹ han, ti wọn si maa n pa ara wọn ni adanu amojukuro.