- Ki ẹni tí a ṣe àbòsí si beere ẹtọ rẹ nípasẹ̀ gbigbe ẹjọ́ lọ ba adajọ ti o ba òfin mu, eleyii kò kó sinu àtakò ti ko dára.
- Ìjiyàn ati àtakò wa ninu awọn ìpalára ahọn ti o maa n ṣe okùnfà ìpín yẹ́lẹyẹ̀lẹ ati ìkọ̀yìn-sí-ara-ẹni láàrin àwọn Musulumi.
- Àtakò ti o dara ni eyi ti o ba jẹ nibi òdodo, ti ọ̀nà ti a gbe e gba naa si dára, o si maa jẹ eyi ti ko dára ti o ba wa fun dida òdodo padà, ati fifi irọ́ rinlẹ, tabi ki o ma si ẹ̀rí kankan fun un.