Lati ọdọ Abu Qataada as-Sulamiyy – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ ma...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe ẹni ti o ba wa si masalaasi ti o si wọle sibẹ ni eyikeyii asiko, ati fun èyíkéyìí erongba, ni ojukokoro la...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ j...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju ninu awọn ẹkọ ti o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wa gbọ khutuba jimọ ni: Didakẹ jẹjẹ fun...
Lati ọdọ ‘Imrān ọmọ Husoyn – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Aisan jẹ̀díjẹ̀dí mu mi, nigba naa ni mo wa bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leer...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye wipe dajudaju ipilẹ ninu irun ni iduro, ayaafi ni igba ti ko ba si ikapa, nigba naa yio ki i ni ẹnit...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ọla ti o n bẹ fun irun ti a ki ni mọsalasi rẹ, pe o lọla ni ẹsan ju ẹgbẹrun irun ti a ki lọ ni ibi ti...
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labid- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i k...
Uthman ọmọ ‘Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- fẹ tun mọsalasi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ni irisi ti o daa ju kikọ akọkọ rẹ lọ, ni awọn en...

Lati ọdọ Abu Qataada as-Sulamiyy – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba wọ masalaasi, ki o yaa ki rakaa meji siwaju ki o to jokoo».

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».

Lati ọdọ ‘Imrān ọmọ Husoyn – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Aisan jẹ̀díjẹ̀dí mu mi, nigba naa ni mo wa bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa irun, ni o wa sọ pe: «Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Irun kan ti a ba ki ni mọsalasi mi yii loore ju ẹgbẹ̀rún irun lọ ti a ki ni ibi ti o yatọ si i afi irun ti a ki ni mọsalasi abeewọ”.

Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labid- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i kalẹ bi o ṣe wa, o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ọlọhun sọ pe: Maa na owó irẹ ọmọ Anọbi Adam, Ọlọhun maa fi òmíràn rọ́pò”.

Lati ọdọ Abu Mas’ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.

Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè".

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ọkùnrin kan wà tó máa ń yá àwọn eniyan ní owo, ó sì máa ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: Ti o bá de ọdọ alaini, ki o ṣamojukuro fun un, bóyá Ọlọ́hun yoo ṣamojukuro fún awa naa, ni ọkunrin yii bá pàdé Ọlọ́hun, Ọlọ́hun sì ṣamojukuro fun un".

Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.