/ Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè

Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè

Lati ọdọ Jabir - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè".
Bukhaariy gba a wa

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe adura ikẹ fun gbogbo ẹniti ó bá jẹ́ onírọ̀rùn, ti o sì jẹ́ ọlọ́rẹ nibi ọja rẹ̀; kò nii lekoko mọ oluraja nibi iye owo ọja, yoo sì maa ba a lo pọ̀ pẹlu ìwà daadaa, tí ó jẹ́ onírọ̀rùn ati ọlọ́rẹ nigba ti o bá rajà; nítorí náà ko nii ṣe àbòsí ki o wa dín iye owó ọjà kù. tí ó jẹ́ onírọ̀rùn ati ọlọ́rẹ nigba ti o bá lọ sin awọn gbese tí ẹlomiran jẹ ẹ; ko nii lekoko mọ tálákà tabi aláìní, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ó maa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ati aanu sin gbese lọwọ wọn ni, ó sì maa lọ́ aláìní lara titi o fi maa ri gbese san.

Hadeeth benefits

  1. Ninu awọn erongba Sharia ni lati dáàbò bo ohun tí o maa ṣatunṣe ajọṣepọ tó wà laarin awọn eniyan.
  2. Ifunni ní iyanju lati maa wùwà rere nibi ajọṣepọ láàárín awọn eniyan bii katakara, ati nkan to jọ bẹẹ.