Lati ọdọ Abu Huraira - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - máa n sọ pé: "Awọn ìrun wakati maraarun, Ir...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fun wa pé dajudaju awọn ìrun ọ̀ranyàn wakati maraarun lojoojumọ, irun Jimọ ni gbogbo ọsẹ, gbigba aawẹ os...
Lati ọdọ Amru ọmọ Shu'aib lati ọdọ baba rẹ lati ọdọ baba baba rẹ, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹ pa awọn ọmọ yin...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju o jẹ dandan lori baba lati pa awọn ọmọ rẹ láṣẹ- lọkunrin ati lobinrin- pẹlu irun ti awọn...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé:...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu hadiiisi Qudusiy pe: Mo pin Suratul Fatiha lori irun laaarin M...
Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaari...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu...
Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kilọ kuro nibi gbigbe irun ọranyan ju silẹ, o si tun sọ pe dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati kiko sin...

Lati ọdọ Abu Huraira - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - máa n sọ pé: "Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá".

Lati ọdọ Amru ọmọ Shu'aib lati ọdọ baba rẹ lati ọdọ baba baba rẹ, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun".

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé: Mo pin irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere o maa jẹ tirẹ, ti ẹru Mi ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi, ti o ba sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), O maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, -O tun maa sọ nígbà miran pe: Ẹru mi fi ọrọ rẹ le Mi lọwọ-, ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), O maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹrú Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem, Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), O maa sọ pe: Eleyii jẹ ti ẹru Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ".

Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”.

Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».

Lati ọdọ Saalim ọmọ Abul Jahd, o sọ pe: Arakunrin kan sọ pé: Ìbá ṣe pé mo ti kírun kí n sì sinmi, bí ẹni pé wọ́n dá a lẹ́bi fún ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Irẹ Bilal, gbe irun duro, fun wa ni ìsinmi pẹlu rẹ”.

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni ti o ṣe pe, ti o ba ti kabara nibi irun, o maa n dakẹ fun igba díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun mo fi baba mi ati iya mi ṣe ìràpadà fún ọ, njẹ o ri idakẹ rẹ laaarin kikabara ati kika Fatiha, ki ni nnkan ti o maa n sọ? O sọ pe "mo maa n sọ pe: Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad".

Lati ọdọ Ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun, ati ti o ba ti kabara fun rukuu, ati ti o ba gbe ori rẹ dide lati rukuu, o maa gbe mejeeji bákannáà, o si maa sọ pé: "Sami'alloohu liman hamidaHu, Robbanaa wa laKal hamdu", ko ki n ṣe bẹẹ nibi iforikanlẹ.

Lati ọdọ Ubaadah ọmọ Saamit - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ko si irun fun ẹni ti ko ba ka Faatiha».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: O maa n kabara nibi gbogbo irun ninu eyi ti o jẹ ọran-anyan ati eyi ti o yatọ si i, ninu Ramadan ati oṣu ti o yatọ si i, o maa n kabara nigba ti o ba dìde, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba rukuu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Robbanaa wa laKal hamdu, ṣíwájú ki o to forikanlẹ, lẹyin naa o maa n sọ pe: Allahu Akbar nigba ti o ba lọ silẹ ni ẹni ti o forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba dide lati ijokoo nibi rakah meji naa; o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo rakah, titi o maa fi pari irun, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba ti n lọ pe : Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ.

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».

Lati ọdọ Jeriir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: A wa lọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa wo òṣùpá ni alẹ ọjọ́ kan- o n túmọ̀ si òṣùpá ọjọ kẹrinla- o wa sọ pe: "Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ, ti ẹ ba ni ikapa ki wọn maa kọdi yin kuro nibi irun ṣíwájú yiyọ oorun ati ṣíwájú wiwọ rẹ, ki ẹ yaa ṣe bẹẹ" lẹyin naa o ka:"(Kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti wíwọ̀ (rẹ̀).)"