- Nkankan o le dipo kika Faatiha yatọ si i pẹlu nini ikapa lati ka a.
- Bibajẹ rakaha eleyii ti wọn o ka Faatiha ninu rẹ, lati ọdọ ẹni ti o finu-findọ ṣe e, ati alaimọkan ati onigbagbe; nitori pe dajudaju origun ni i, ati pe awọn origun o lee bọ lailai.
- Kika Faatiha o maa bọ fun ero ẹyin nigba ti o ba ba imaamu ni rukuu.