- Ninu awọn ọgbọn ti o n bẹ fun gbigbe ọwọ mejeeji soke nibi irun ni pe o jẹ ọṣọ fun irun ati igbetobi fun Ọlọhun- mimọ ni fun Un-.
- Gbigbe ọwọ rẹ mejeeji soke fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ rẹ̀ - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi aaye ikẹrin gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ẹgbawa Abu Hamid As-Saa'idiy lọdọ Abu Daud ati ẹni ti o yàtọ̀ si i, oun ni nibi idide lati ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta ati mẹrin.
- O fi ẹsẹ rinlẹ bakannaa lati ọdọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe o maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee eti rẹ mejeeji laini fi ọwọ kan an gẹgẹ bi o ṣe wa ninu ẹgbawa Maalik ọmọ Al-Huwairith ninu sọhihu mejeeji pé: "Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba kabara o maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè titi tí o maa fi ṣe deedee eti rẹ mejeeji pẹlu wọn"
- Adapọ laaarin ṣíṣe Sami'alloohu liman hamidaHu ati Robbanaa wa laKal hamdu jẹ ti imam ati oluda-irun-ki nìkan, ṣùgbọ́n ero ẹyin imam maa sọ pé: Robbanaa wa laKal hamdu.
- Sisọ pe: "Robbanaa wa laKal hamdu" lẹyin rukuu ni alaafia lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe awọn ọna mẹrin kan ni a le gba sọ ọ, ati pe eleyii jẹ ọkan ninu rẹ, eyi ti o daa julọ ni ki ọmọniyan tọ ipasẹ àwọn agbekalẹ yii, ki o si mu eyi wa ni ẹẹkan, ati òmíràn wa nigba mii.