/ “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”

“Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”

Lati ọdọ Buraida- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”.
Tirmiziy ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju adehun ati majẹmu ti o wa laaarin awọn Musulumi ati laaarin awọn ti wọn yatọ si wọn ninu awọn alaigbagbọ ati awọn ṣọbẹ-selu ni irun kiki, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ.

Hadeeth benefits

  1. Titobi ipo irun, ati pe oun ni ipinya ti o wa laaarin olugbagbọ ati alaigbagbọ.
  2. Fifi awọn idajọ Isilaamu rinlẹ pẹlu nnkan ti o ba han ninu isẹsi awọn eniyan yatọ si eyi ti o pamọ.