Lati ọdọ Hitton ọmọ Abdullahi Ar-Roqooshiy o sọ pe: Mo kirun kan pẹlu Abu Musa Al-Ash'ariy, nigba ti o wa lori ìjókòó, arakunrin kan ninu ijọ sọ pe: Wọn ti da irun pọ mọ ṣíṣe daadaa ati saka, o sọ pe: Nigba ti Abu Musa kirun tan ti o si salamọ, o kọ ju sẹ́yìn, ni o wa sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? O sọ pe: Ni awọn èèyàn ba dakẹ, lẹyin naa o sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? Ni awọn èèyàn ba dakẹ, o sọ pe: Boya iwọ Hitton lo sọ ọ? O sọ pe: Mi ko sọ ọ, mo bẹru pe ki o ma bu mi nitori rẹ, arakunrin kan ninu wa sọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ pe: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ nibi irun yin ni? Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀ ti o si ṣàlàyé sunnah wa fun wa ti o si kọ wa ni irun wa, o wa sọ pe: "Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara, ti o ba sọ pe: (Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7), ki ẹ sọ pé: Aamiin, Ọlọhun maa da yin lóhùn, ti o ba ti kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu, dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín, yio si gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamd, Ọlọhun maa gbọ́ yín, dajudaju Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sami'alloohu liman hamidaHu, ti o ba ti kabara ti o forikanlẹ, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si forikanlẹ, dájúdájú imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú yín, o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba ti wa lori ìjókòó, ki ọrọ akọkọ ẹni kọọkan ninu yin jẹ: At-tahiyyatu t-tayyibaatus-salawaatu lillah, as-salamu ‘alayka ayyuha’n-Nabiyyu wa rahmatulLaahi wa barakatuhu, as-salamu ‘alayna wa alaa ibaadil Laahis sọọlihiin, ash'hadu an laa ilaaha illal Loohu wa ash'hadu anna Muhammadan abduhuu wa rọsuuluhuu".