Lati ọdọ ‘Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “ko si irun pẹlu ikalẹ o...
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi kiki irun pẹlu ikalẹ ounjẹ ti ẹmi olukirun n fa síbẹ̀, ti ọkan rẹ si n so mọ ọn. Gẹgẹ...

Lati ọdọ ‘Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n”.

Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”.

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ṣe ẹnikọọkan yin o maa bẹru - tabi: Ẹnikọọkan yin o bẹru - nigba ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu, ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan di aworan Kẹtẹkẹtẹ».

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ, ti ko si mọ iye ti o ki boya mẹta ni tabi mẹrin, ki o yaa ju iyemeji naa nù, ki o mọ irun rẹ lori nnkan ti o da a loju, lẹyin naa, o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ, ti o ba ki marun-un wọn maa ṣe irun rẹ ni nǹkan ti eéjì le pin fun un, ti o ba ki i lati pe mẹrin, mejeeji maa jẹ iyẹpẹrẹ fún èṣù".

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".

Lati ọdọ Thaoban- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n wa aforijin lẹẹmẹta, o maa sọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom”, Al-Waleed sọ pé: Mo sọ fun Al-‘Aozaa’iy: Bawo ni a ṣe maa n wa àforíjìn? O sọ pe: Waa sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah.

Lati ọdọ Abu Zubayr, o sọ pe: Ibnu Zubayr jẹ ẹniti o maa n sọ ni ẹyin ìrun kọọkan nigba ti o ba salamọ pe: “Laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharīka lahu, lahul mulku wa lahul hamdu wa huwa ala kulli shay’in qodīr, laa haola walā quwwata illā biLlāh, lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu, lahu ni‘matu wa lahul fadlu wa lahuu thanāhul hasan, lā ilāha illā Allāhu mukhlisiina lahuu dīna wa lao karihal kāfirūna”, o wa sọ pe: «Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan».

Lati ọdọ Warrood olukọwe Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah, o sọ pe: Al-Mugiiroh ọmọ Shu’bah pe àpèkọ fun mi ninu iwe kan si Mu’aawiyah pe: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ lẹyin gbogbo irun ọran-anyan pe: “Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, laHul mulku wa laHul hamdu, waHuha ‘ala qulli shai’in Qodeer, Allahumo laa maania limaa ‘atoita, wa laa mu’tiya limaa mana’ta, wa laa yanfa’u dhal jaddi minKal jaddu”.

Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-: «Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun».

Lati ọdọ Abu Umāmah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku.

Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, ati rakah meji ṣíwájú irun Subhi; o jẹ asiko kan ti wọn ko ki n wọle ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Hafsoh sọ fun mi pe ti oluperun ba ti pe irun ti alufajari ba si ti yọ, o maa ki rakah meji, o wa ninu ẹgbawa kan pé: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ki rakah meji lẹyin irun jimọh.