- Pataki ipaya ati wiwa ọkan lori irun, ati pe dajudaju Shaitan maa n gbiyanju lati da ìrun rú ati lati jẹ ki èèyàn maa ṣe iyèméjì lórí ìrun.
- Ṣíṣe wiwa iṣọra kuro lọdọ Shaitan lofin nibi royiroyi rẹ lori irun, pẹlu títu itọ́ si ẹgbẹ osi lẹẹmẹta.
- Alaye nipa nnkan ti awọn sahaabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- wa lori rẹ ninu ṣiṣẹri pada wọn sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi nnkan ti o ba n ṣẹlẹ̀ si wọn ninu awọn ìṣòro titi yoo fi wa ojútùú si i fun wọn.
- Wíwà ni ààyè ọkan awọn saabe, ati pe ohun ti o mumu laya wọn ni ọrun.