Lati ọdọ Aaisha Iya awọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, y...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wẹ janaba yio bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, Lẹyin naa ni yio wa ṣe aluwala gẹgẹ...
Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ si irin-ajo kan fun awọn bukaata rẹ kan, ni janaba ba ṣẹlẹ si...
Lati ọdọ Al-Mughiirah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe. Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni irin-ajo kan, ni mọ ba bẹrẹ lati bọ abọs...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ni ọkan ninu awọn irin-ajo rẹ, ni o wa ṣe aluwala, Nigba ti o wa débi fifọ ẹsẹ mejeeji, Al- Mughiirah ọmọ...
Lati ọdọ Aaisha iya àwọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Faatimah ọmọ Abu Hubaysh bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere o wa sọ pe...
Faatimah ọmọ Hubaysh beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa sọ pe: Dajudaju ẹjẹ o ki n da lara mi ati pe o si maa n wa titi di ig...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ti nkankan ba n ru ninu iku ẹni ti n kirun, ti ko wa mọ boya nkan jade tabi nkankan o ja...

Lati ọdọ Aaisha Iya awọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.

Lati ọdọ Ammār ọmọ Yāsir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ran mi ni iṣẹ kan, ni mo ba ni janaba ti mi o si ri omi, ni mo ba po ara mọ erupẹ gẹgẹ bi ẹranko ṣe maa n po ara mọ ọn, lẹyin naa ni mo wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ni mo si sọ iyẹn fun un, o si sọ pe: «O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ».

Lati ọdọ Al-Mughiirah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe. Mo wa pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni irin-ajo kan, ni mọ ba bẹrẹ lati bọ abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji, ni o wa sọ pe: «Fi wọn silẹ, nitori pe dajudaju mo ti mejeeji bọ ọ ni mimọ ni» ni o wa fi ọwọ pa mejeeji.

Lati ọdọ Aaisha iya àwọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Faatimah ọmọ Abu Hubaysh bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere o wa sọ pe: Dajudaju mo jẹ ẹni ti maa n ri ẹjẹ awaada ti mii si ki n si ni imọra, njẹ mo le fi irun silẹ? Ni o wa sọ pe: «Rara, dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun».

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ri nkankan ninu ikun rẹ, ti o wa ru u loju boya nkankan jade nibẹ tabi ko jade, ki o ma ṣe jade kuro ni masalaasi titi ti yio fi gbọ ohun, tabi ki o gbọ oorun».

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ti oluperun ba sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti ẹnikẹni ninu yin naa wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu an laa ilaaha illa Allāhu, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Ash'adu anna Muhammadan rọsuuluLlaah, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘ala sọlaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Hayya‘alal falaah, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa haola walā quwwata illā biLlāh, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Allāhu Akbar Allāhu Akbar, lẹyin naa o (oluperun) tun wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, ti o (olugbọ) wa sọ pe: Laa illaha illā Allāhu lati inu ọkan rẹ wa yio wọ aljanna».

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».

Lati ọdọ Sadu ọmọ Abi waqqoosi, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ ojisẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in.

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti yio fa mi wa si mọṣalaṣi, ni o wa bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere ki o ṣe ẹdẹ fun un ki o maa kirun ni inu ile rẹ, ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: «Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?" wọn sọ pe: Ko lee ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ, o sọ pe: "Gẹgẹ bẹẹ ni iru awọn irun maraarun-un, Ọlọhun maa n pa awọn àṣìṣe rẹ pẹlu rẹ".

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun" o sọ pe: O sọ wọn fun mi, ti mo ba wa alekun rẹ dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.

Lati ọdọ 'Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀".