- Jijẹ nǹkan ti a ṣe lofin pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji a maa ṣẹlẹ nibi ṣiṣe aluwala latara ẹgbin kekere, amọ wiwẹ fun ẹgbin nla ko si ibuyẹ kuro nibi fifọ ẹsẹ mejeeji.
- Pipa o maa jẹ ẹẹkan pẹlu mimu ọwọ ti o ti rin fun omi lọ bọ lori abọsẹsẹ alawọ yatọ si isalẹ rẹ.
- Wọn ṣe ni majẹmu fun pipa abọsẹsẹ alawọ mejeeji ki wiwọ rẹ o jẹ lẹyin aluwala ti o pe ti yio fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ninu rẹ, ati pe ki abọsẹsẹ alawọ naa o mọ, ki o si tun bo aaye ọranyan nibi ẹsẹ, ki pipa a na o waye nibi ẹgbin kekere, ki o ma jẹ nibi janaba tabi nkan ti o le sọ iwẹ di dandan, ati pe ki pipa naa o maa waye laarin asiko ti a là kalẹ ninu shariah oun naa ni ọjọ kan pẹlu oru kan fun onile ati ọjọ mẹta pẹlu oru rẹ fun arinrin-ajo.
- Wọn o fi jọ ibọsẹ alawọ mejeeji gbogbo nkan ti o ba ti le bo ẹsẹ bi ibọsẹ olowuu ati nkan ti o yatọ si i, nitori naa o lẹtọọ lati fi ọwọ pa a.
- Didaa iwa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati ikọnilẹkọọ rẹ, latari pe o kọ fun Al-Mughiirah lati bọ ibọsẹ alawọ mejeeji, ti o si tun ṣe alaye idi rẹ fun un: Wipe dajudaju o wọ mejeeji ni mimọ; ki ẹmi rẹ le balẹ, ki o si tun mọ idajọ.