Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati...
Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe aluwala ni ẹyọkọọkan.
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti o ṣe pe ni awọn igba miran ti o ba ṣe aluwala yio fọ oríkèé kọọkan ninu awọn oríkèé ara rẹ ni ẹẹkan...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Zaid- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji.
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba mii ti o ba fẹ ṣe aluwala, o maa n fọ gbogbo orikee ninu awọn orikee aluwala lẹẹmeji, o maa fọ oju- ti...
Lati ọdọ Humraan ẹru Uthman ọmọ ‘Affan pé o ri Uthman ọmọ ‘Affan ti o beere fun omi aluwala, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba rẹ, o fọ mejeeji lẹẹmẹta,...
Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- kọ wa ni bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n ṣe aluwala pẹlu oju ọna fifi ṣe iṣẹ ṣe; ki o le baa kun ni...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn idajọ imọra, ninu wọn ni: Akọkọ: Dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala, o jẹ dandan fun...
Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa sọ pe: Bawo ni ẹyin ṣe maa n ṣe? O sọ pe: Aluwala ẹyọkan maa n to fun ẹnikẹni ninu wa lopin igba ti ko ba ti dá ẹgbin.
Lati ọdọ Humraan ẹru Uthman ọmọ ‘Affan pé o ri Uthman ọmọ ‘Affan ti o beere fun omi aluwala, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba rẹ, o fọ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ ọtun bọ inu omi aluwala, lẹyin naa o fi omi yọ ẹnu rẹ o si fin in simu o si fin in síta, lẹyin naa o fọ oju rẹ lẹẹmẹta, ati ọwọ rẹ mejeeji titi de igunpa rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o pa ori rẹ, lẹyin naa o fọ gbogbo ẹsẹ rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o sọ pe: Mo ri Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yìí, o wa sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in”.
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri, ti ẹnikẹni ninu yin ba ji lati oju orun rẹ ki o yaa fọ ọwọ rẹ ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu omi aluwala rẹ, nitori pe ẹnikẹni ninu yin ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju". Ati ẹgbawa Muslim: "Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti ji lati oju orun rẹ, ki o ma ti ọwọ rẹ bọ inu igba titi yoo fi fọ ọ lẹẹmeta, nitori pe ko mọ ibi ti ọwọ rẹ wa mọju".
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọja nibi saare meji kan, ni o wa sọ pe: «Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri» lẹyin naa ni o wa mu imọ ọpẹ tutu o si ya a si meji, ti o si tun ri ẹyọ kọọkan mọ saare kọọkan, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni idi ti o fi ṣe eleyii? O sọ pe: «O ṣee ṣe ki wọn o ṣe iya awọn mejeeji ni fufuyẹ lopin igba ti wọn o ba tii gbẹ (imọ ọpẹ)».
Lati ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi».
Lati ọdọ Aisha - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Pákò jẹ́ imọtoto fun ẹnu, ó sì jẹ́ okunfa iyọnu Oluwa".
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ bayi pe: Ti ki báa ṣe pe kin má ko waala bá awọn olugbagbọ ododo ni - tabi awọn ijọ mi ni - mi o ba pa wọ́n laṣẹ lati máa rin pako ni gbogbo asiko Irun kọọkan.
Lati ọdọ Abu Hurayra o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ».
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Adamọ marun-un lo jẹ: Dida abẹ ati fifa irun abẹ ati gige tubọmu ati gige awọn èékánná ati fifa irun abiya”.
Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala ". O n bẹ fun Bukhari: O sọ pe: "Ṣe aluwala ki o si fọ nnkan ọmọkunrin rẹ".