- Ofofo ati gbigbe imọran kuro nibi itọ jusilẹ wa ninu awọn iya ẹṣẹ ati ninu awọn okunfa iya saare.
- Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ṣe isipaya apakan ni awọn nkan ikọkọ - gẹgẹ bii iya saare - lati ṣe afihan àmì jijẹ anabi rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
- Iṣe yii iyẹn ni yiya imọ ọpẹ si meji ati fifi i si ori saare jẹ ẹsa fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; nitori pe dajudaju Ọlọhun ti fi han an ìṣesí awọn ti wọn wa ninu saare naa, nitori naa a ko le fi ẹni ti o yatọ si i (Anabi) ṣe deede rẹ, nitori pe ko si ẹni ti o mọ ìṣesí awọn ti wọn wa ninu saare.