- Ṣiṣe fifọ ọwọ mejeeji ni nnkan ti a fẹ ṣíwájú titi mejeeji bọ inu igba ni ibẹrẹ aluwala, ti o ba ṣe pe ko dide lati ojú orun, ṣùgbọ́n ti o ba ṣe pe o ji lati oju orun oru, fifọ mejeeji jẹ dandan.
- O tọ fun olukọ lati tọ oju ọna ti o sunmọ julọ sibi agbọye ati irinlẹ imọ lọdọ oluwa imọ, ninu ìyẹn ni kikọ awọn eniyan lẹkọọ pẹlu iṣe.
- O tọ fun olukirun lati ti awọn ero ti wọn so pọ mọ awọn airoju aye dànù, ati pe pipe irun n bẹ nibi ki ẹmi wa nibẹ, ti ko ba ri bẹ́ẹ̀, àtilà nibi awọn ero maa n ṣoro, o wa jẹ dandan fun un lati ja ẹmi rẹ logun ki o si ma túra silẹ nibi ìyẹn.
- Ṣíṣe bibẹrẹ pẹlu apa ọtun ni nnkan ti a fẹ nibi aluwala.
- Ṣíṣe titotẹlera laaarin fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi simu ati fifin in sita lofin.
- Ṣíṣe fifọ oju ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji lẹẹmẹta ni nnkan ti a fẹ, ati pe eyi ti o jẹ dandan ni fifọ wọn lẹẹkan.
- Aforijin Ọlọhun fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ wa lori akojọpọ alamọri méjì: Aluwala, ati kiki rakah méjì, lori iroyin ti wọn darukọ ninu Hadiisi.
- Aala n bẹ fun gbogbo orikee ara kọọkan ninu awọn orikee aluwala: Aala oju ni: Lati ibi ti irun ori ti bẹ̀rẹ̀, titi de ibi ti o wálẹ̀ ninu irungbọn ati agbọn ni òró, ati lati eti kan si keji ni ibu. Aala ọwọ ni: Lati awọn eteeti awọn ọmọnika titi de igunpa, oun ni ibi asopọ laaarin ọwọ ati apa. Aala ori ni: Lati ibi ti irun ti maa n saaba hù nibi ẹgbẹ oju si oke ọrun, ati pe pipa eti mejeeji wa lara ori. Aala ẹsẹ ni: Gbogbo ẹsẹ pata pẹlu ibi asopọ ti o wa laaarin rẹ ati laaarin ojugun.