Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Zaid- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe aluwala lẹẹmeji meji.
Bukhaariy gba a wa
Àlàyé
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba mii ti o ba fẹ ṣe aluwala, o maa n fọ gbogbo orikee ninu awọn orikee aluwala lẹẹmeji, o maa fọ oju- ti gbigbo ẹnu ati fifa omi simu n bẹ nibẹ- ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji lẹẹmeji.
Hadeeth benefits
Eyi ti o jẹ dandan ni fifọ awọn orikee lẹẹkan ati pe eyi ti o ba lekun jẹ nnkan ti a fẹ.
Ṣíṣe lofin ṣíṣe aluwala lẹẹmeji meji nigba mii.
Nnkan ti a ṣe lofin nibi pipa ori ni ẹẹkan.
Share
Use the QR code to easily share the message of Islam with others