Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: "Ọ...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun kọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kadara awọn ẹda ni ifọsiwẹwẹ ninu isẹmi ati iku ati...
Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Mas’huud- ki Ọlọhun yọnu si i-: Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún...
Ibnu Mas’ud sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀, olódodo ni nibi ọ̀rọ̀ rẹ, ẹni tí wọ́n sọ òdodo fun ni; torí pé Ọlọhu...
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – fún wa niroo pé Alujanna ati Ina súnmọ́ ènìyàn gẹgẹ bi okùn bàtà tó máa n wà lókè ẹsẹ̀ ṣe súnmọ́, nitori pé...
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé dajudaju awọn nkan tí ẹ̀mí eniyan n fẹ́ ni o wa ní ayika Iná ọ̀run, gẹgẹ bii ṣiṣe awọn nkan...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun, nigba ti O da alujanna ati ina, O sọ fun Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pé: Lọ si al...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: "Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun, o sọ pe: Aga ọla Rẹ wa ni ori omi".
Láti ọ̀dọ̀ Abdullah ọmọ Mas’huud- ki Ọlọhun yọnu si i-: Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà yóò di ẹjẹ dídì fun ogójì ọjọ́, lẹyin naa yoo di baaṣi ẹran fun ogójì ọjọ́, lẹ́yìn náà wọn maa ran malaika si i, wọ́n maa pa a láṣẹ pẹ̀lú gbólóhùn mẹrin kan, wọn maa waa kọ: Arisiki rẹ, ati àsìkò rẹ, ati iṣẹ rẹ, ati pe ṣe oloriburuku ni abi oloriire, lẹ́yìn naa wọn maa fẹ́ ẹ̀mí si i lára, dájúdájú ẹnikan ninu yin yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin alujanna ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ iná, yoo si wọ ọ, dájúdájú ẹnikan nínú yin, yoo maa ṣe iṣẹ́ ọmọ ina, titi ti ohun ti o ṣẹku láàrin rẹ ati láàrin iná ko fi nii ju apá lọ, àkọsílẹ̀ maa wa borí rẹ, yoo waa maa ṣe iṣẹ́ ọmọ alujanna, yoo si wọ̀ ọ́”.
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀".
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: "Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna".
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla maa ba a- lọ sí alujanna, O wa sọ pé: Wò ó, ki o si wo ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fun awọn ọmọ alujanna ninu rẹ. Ni o ba wo o, o si ṣẹri pada, ni o wa sọ pe: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa gbọ nipa rẹ ti ko nii wọ̀ ọ́. Ni O ba pàṣẹ ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika rẹ, O wa sọ pé: Tún lọ sibẹ, ki o si wo o ati ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fún àwọn ọmọ alujanna nínú rẹ̀. Ni o wa wo o, o si ba a pe wọn ti fi àwọn ohun tí ẹ̀mí korira rọkirika rẹ, o wa sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ẹ̀rù n ba mi ki ẹni kankan ma wọ ibẹ̀. O sọ pé: Lọ wo ina ati ohun ti Mo pèsè kalẹ fun awọn ọmọ ina nínú ẹ. O wo inu rẹ, ni o wa ri i ti o n gun ara wọn, o ṣẹri pada, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa wọ̀ ọ́. Ni O wa ni ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi maa n gbádùn rọkirika rẹ, o padà, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹni kankan má là kúrò nibẹ ayafi ki o wọ̀ ọ́”.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, iná ayé gan ti tó. O sọ pe: “Ina Jahannama ju ti aye lọ pẹ̀lú ẹ̀yà mọkandinlaadọrin, gbígbóná ọkọọkan ninu ẹ da gẹgẹ bii gbígbóná iná ayé”.
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?».
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọle ti mi, mo si ti bo apoti iko-nnkan-si ti o jẹ temi pẹlu aṣọ kan ti awọn aworan n bẹ nibẹ, nigba ti o wa ri i, o fa a ya ti oju rẹ si pọn, o wa sọ pe: "Irẹ 'Aaisha, Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun" 'Aaisha sọ pe: "A si ge e, a si sọ ọ di irọri kan tabi irọri méjì".
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ".
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun àbúrò bàbá rẹ̀ pé: “Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde”, o sọ pe: Ti kii ba ṣe pe àwọn Quraysh maa bu mi ni, ti wọn maa sọ pé: Ìbẹ̀rù ni o mu un sọ ọ́, mi o ba fi dùn ọ́ nínú. Ni Ọlọhun wa sọ aaya yii kalẹ̀: {Dájúdájú ìwọ kò lè fi ọ̀nà mọ ẹni tí o fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Allāhu l’Ó ń fi ọ̀nà mọ ẹni tí Ó bá fẹ́} [Al-Qasas: 56].
Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amr, ki Olohun yọnu si awọn mejeeji, o sọ pe: Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ , ife rẹ̀ sì dà bii ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ẹni tí ó bá mu nínú ẹ, òùngbẹ kò nii gbẹ ẹ́ láéláé.”
Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára, olupepe kan maa pè pé: Ẹ̀yin ọmọ alujanna, wọn maa garùn wọn si maa wò, yoo wa sọ pé: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, lẹyin naa o maa pe pe: Ẹyin ọmọ iná, wọ́n maa garùn wọ́n sì maa wò, o maa waa sọ pe: Ǹjẹ́ ẹ mọ èyí? Wọn maa sọ pé: Bẹẹni, èyí ni ikú, gbogbo wọn ni wọ́n si ti ri i, wọn maa du u, lẹyin naa o maa sọ pé: Ẹyin ọmọ alujanna, gbére, ko si ikú mọ, ẹyin ọmọ iná, gbére, ko si ikú mọ, lẹyin naa ni o ka: {Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná} [Maryam: 39], àwọn wọ̀nyí wa ninu igbagbera ni àwọn ará ayé, {wọn kò sì gbàgbọ́} [Maryam: 30]”.