Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàré...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ kuro nibi jijokoo si ori awọn sàréè.
Gẹgẹ bi o ṣe kọ kuro nibi kiki irun si awọn sàréè, bii ki sàréè o...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju awọn malaika o nii wa pẹlu ikọ arin irin-ajo kan ti aja n bẹ pẹlu wọn, tabi agogo ti...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta...
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọrọ nipa iwosan ti o ṣe anfaani fun awọn ibeere ti èṣù fi n ko royiroyi ba olugbagbọ, Èṣù o maa sọ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹni...
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo ninu hadīth qudusiy pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn sọ pe: Ẹni ti o ba fi suta kan aa...
Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waas...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe waasu kan ti o de ogongo fun awọn saabe, ti awọn ọkan gbọn ti awọn oju dami latara rẹ, Wọn sọ pe: Irẹ oji...
Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara».
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn ».
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ.
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ, àti pe ẹru Mi ko nii yẹ ko nii gbo lẹni ti yio maa sunmọ Mi pẹlu awọn aṣegbọrẹ titi ti maa fi nífẹ̀ẹ́ rẹ, ti Mo ba ti wa nífẹ̀ẹ́ rẹ: Maa di igbọrọ rẹ ti yoo fi maa gbọrọ, maa di iriran rẹ ti yio fi maa riran, maa si di ọwọ rẹ ti yio fi maa mu nkan, Maa si tun di ẹsẹ rẹ ti yio fi maa rin, ti o ba wa bi Mi leere maa fun un, ti o ba si tun wa iṣọra pẹlu Mi maa sọ ọ, Mi o fa sẹyin nibi nkankan ti Mo fẹ ṣe bii ifasẹyin Mi nibi gbigba ẹmi mumini, ti o n korira iku ti Emi naa si n korira fifi ara ni in».
Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waasu kan ti o de ògòńgó fun wa ti awọn ọkan ń gbọn riri latara rẹ, ti awọn oju n dami latara rẹ, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o ṣe waasu idagbere fun wa, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun wa. O sọ pe: "Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin, ẹ di wọn mu pẹlu eyin ọgan, ẹ ṣọra fún awọn adadaalẹ, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni".
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba ja ni abẹ àsìá kan ti o fọ́jú, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya, tabi o n pepe lọ sibi ẹlẹyamẹya, tabi o n ran ẹlẹyamẹya ṣe, wọn wa pa a, o jẹ pipa kan ti o jẹ ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba jade si ijọ mi, ti o n pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pipa olugbagbọ rẹ, ti ko pe adehun rẹ fun aladehun, ko si ninu ijọ mi, emi naa ko si ninu ijọ rẹ”.
Láti ọ̀dọ̀ Mah’qil ọmọ Yasaar Al-Muzaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”.
Lati ọdọ Umu salamah iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Awọn adari kan maa jẹ, ẹ maa mọ ẹ si maa ṣe atako, ẹni ti o ba mọ, o ti bọ, ẹni ti o ba ṣe atako, o ti la, sugbọn ẹni ti o ba yọnu ti o si tẹle" wọn sọ pe: Njẹ a ko nii ba wọn ja? O sọ pe: "Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n kirun".
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin".
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ 'Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Gbogbo yín ni adaranjẹ, ẹni ti a maa beere awọn ti o dajẹ lọwọ rẹ ni ẹni kọọkan yín,, adari fun awọn eniyan jẹ adaranjẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ọkunrin ni adaranjẹ lori awọn ara ile rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, obinrin ni adaranjẹ lori ilẹ baale rẹ ati ọmọ rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa wọn, ẹru jẹ adaranjẹ lori dukia olowo rẹ, oun ni wọn maa bi leere nipa rẹ, ẹ tẹti ẹ gbọ́, gbogbo yin ni adaranjẹ ati pe gbogbo yin ni wọn maa bi leere nipa ẹni ti o dajẹ".
Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe: “Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”.
Lati ọdọ Tamiim Ad-Daariy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.