- Hadiisi naa wa ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti o sọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu ìjọ rẹ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.
- Ṣíṣe lẹtọọ sisọ fun ẹni ti adanwo fẹ kan nípa nnkan ti wọn maa mu ṣẹlẹ̀ si i ninu àdánwò; lati pese ara rẹ kalẹ, ti o ba ti wa de ba a yoo jẹ onisuuru ti o maa reti ẹsan lati ọdọ Ọlọhun.
- Idirọmọ Kuraani ati sunnah maa n mu ni jade kuro nibi awọn fitina ati iyapa.
- Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbọ ati itẹle fun awọn adari pẹlu daadaa, ati aima jade le wọn lori, ko da ki abosi ṣẹlẹ̀ lati ọdọ wọn.
- Lilo ọgbọ́n ati itẹle sunnah ni asiko awọn fitina.
- O jẹ dandan fun ọmọniyan lati ṣe ẹtọ ti o jẹ dandan fun un, ko da ki nnkan kan ṣẹlẹ̀ si i ninu abosi.
- Ẹri n bẹ nibẹ lori ipilẹ: Ṣíṣe ẹsa eyi ti o rọrun julọ ninu aburu meji tabi eyi ti o fuyẹ julọ ninu inira meji.