- Àdéhùn ìjìyà yii kii ṣe ti imaamu agba nìkan ati àwọn aṣojú rẹ, bi ko ṣe pe o kari gbogbo ẹni tí Ọlọhun ba ni ki o maa darí àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ.
- Ohun ti o jẹ dandan fun ẹni ti Ọlọhun ba ni ki o jẹ alaṣẹ fun nǹkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ni ki o gba wọn ni ìmọ̀ràn, ki o si gbìyànjú láti pe agbafipamọ, ki o si ṣọ́ra fun ìjàǹbá.
- Titobi ojúṣe gbogbo ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ gbogbogboo tabi ti ara ẹni, o tobi ni tabi o kere.