- Itẹle awọn adari jẹ dandan nibi nnkan ti o yatọ si ṣiṣẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-.
- Ikilọ ti o le koko n bẹ fun ẹni ti o ba jade kuro nibi itẹle olori, ti o si tu ìjọ Musulumi ká, ti o ba ku lori isẹsi yìí, o ku lori oju ọna awọn asiko aimọkan.
- Kikọ kuro nibi jija ija ẹlẹyamẹya n bẹ ninu hadiiisi náà.
- Jijẹ dandan pipe adehun.
- Oore topọ n bẹ ninu itẹle ati wiwa pẹlu awọn ijọ, ati ifọkanbalẹ ati ifayabalẹ, ati dida ni awọn isẹsi.
- Kikọ kuro nibi fifi ara wé awọn èèyàn asiko aimọkan.
- Pipaṣẹ pẹlu didunnimọ janmọọn awọn Musulumi.