- Ṣiṣẹri kuro nibi royiroyi èṣù ati awọn èrò rẹ ti maa n wa si ẹmi, ati aironu nipa rẹ, ati sísádi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lati mú u lọ.
- Gbogbo nnkan ti o ṣẹlẹ̀ ninu ọkan ọmọniyan ninu awọn royiroyi ti wọn yapa ofin wọn wa lati ọdọ èṣù.
- Kikọ kuro nibi ìrònú nipa paapaa Ọlọhun, ati ṣisẹnilojukokoro lori ìrònú nipa awọn ẹda Rẹ ati awọn ami Rẹ.