Lati ọdọ Jundub, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wí...
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n fun wa ni iro nipa ipo rẹ̀ lọdọ Ọlọhun Ọba, ó n sọ pé ipo naa dé ipo ifẹ tó ga julọ, gẹgẹ bi Anabi Ibrahim...
Lati ọdọ Abu Al-Hayyaaj Al-Asadiy, o sọ pe: Aliy ọmọ Abu Tọọlib sọ fun mi pe: Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ran àwọn saabe rẹ pe ki wọn ma fi ère- oun ni aworan nǹkan ti o ni ẹmi ti o jẹ abara tabi eyi ti ko ni...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ikilọ kuro nibi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, oun ni fifuramọ aburu latara eyikeyii nnkan kan ti a le gbọ́ lo j...
Lati ọdọ Imraan ọmọ Husayn- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ...
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe adehun iya fun ẹni ti o ba ṣe àwọn nǹkan kan ninu ijọ rẹ pẹlu gbólóhùn rẹ pe: “Kii ṣe ara wa”, ninu rẹ n...
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daa...
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju akoran ti èèyàn asiko aimọkan ni adisọkan rẹ pe dajudaju aisan maa n ṣi kuro fun ara rẹ bọ si...
Lati ọdọ Jundub, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wípé: “Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo, ti emi ba ti ẹ fẹ mu ẹnikan ninu awọn ijọ mi ni ọrẹ aayo, emi i ba mu Abu Bakr ni ọrẹ aayo, ẹ gbọ o, dajudaju awọn ijọ tí wọ́n ti lọ síwájú yin a maa mú saare awọn Anabi ati awọn ẹniire inu wọn ni mọṣalaṣi, nitori naa, ẹ má ṣe mú awọn saare ni mọṣalaṣi, dajudaju emi n kọ ọ fún yín”.
Lati ọdọ Abu Al-Hayyaaj Al-Asadiy, o sọ pe: Aliy ọmọ Abu Tọọlib sọ fun mi pe: Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba.
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun.
Lati ọdọ Imraan ọmọ Husayn- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn, ati ẹni tí ó bá ta kókó kan, ẹni tí ó bá wa ba ẹni tí n pe apemọra imọ kọ̀kọ̀, ti o wa gba ohun ti o sọ gbọ́, onítọ̀hún ti ṣe aigbagbọ si nǹkan ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun Muhammad, ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a”.
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa".
Lati ọdọ Zaid bn Khalid Al-Juhaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki irun asunbaa fun wa ni Hudaibiyah lẹ́yìn ojo ti o rọ̀ ni òru, lẹ́yìn tí ó kírun tán, o kọju si awọn eniyan, o sọ pe: “Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ, ẹni tí ó bá sọ pé: Wọ́n rọ òjò fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati aanu Rẹ, ìyẹn ni ẹni tí ó gbagbọ ninu Mi ti o si ṣe aigbagbọ si ìràwọ̀, ṣugbọn ẹni tí o ba sọ pe: Pẹ̀lú ìràwọ̀ bayii bayii, ìyẹn ni ẹni tí o ṣe aigbagbọ ninu Mi, ti o wa ni igbagbọ ninu ìràwọ̀”.
Lati ọdọ ‘Uqbah ọmọ ‘Aamir Al-Juhaniy - ki Ọlọhun yọnu si i: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ikọ kan wa ba a, ti o si gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan ninu wọn ti o ka ọwọ duro fun ẹnikan, ni wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o gba ọwọ adehun (ibura) mẹsan o si fi eleyii silẹ? O sọ pe: «Dajudaju agbekọ n bẹ lara rẹ», ni o (arakunrin yẹn) wa ti ọwọ rẹ wolẹ ti o si fa a ja, nigba naa ni o (Anabi) wa gba ọwọ adehun (ibura) rẹ, ni o wa sọ pe: «Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)».
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'hud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”
Lati ọdọ àwọn kan ninu awọn ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ”.
Lati ọdọ ọmọ umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó ní oun gbọ lẹnu ọkunrin kan ti n sọ pe: Rara o, oun fi Kaabah búra, ọmọ umar wa sọ fun un pe: A kò gbọdọ̀ fi nnkan tó yatọ si Ọlọhun Allah búra, tori dajudaju emi gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pe: "Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ."
Lati ọdọ Huzaifah- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ".
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun wọn ni ọjọ igbedide ti wọn ba ti san awọn eniyan lẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ti ẹ maa n ṣe karimi fun ni aye, ki ẹ si wo boya ẹ maa ri ẹsan kankan lọdọ wọn?"