- Ṣíṣe iṣẹ yẹmiwo ni eewọ, ati lílọ ba àwọn yẹmiwo, ati bibi wọn nipa kọ̀kọ̀.
- Èèyàn lè má gba ẹ̀san itẹle àṣẹ Ọlọhun ki o le jẹ ìjìyà fun un lórí ẹṣẹ.
- O maa ko sinu hadiisi naa nǹkan ti a n pe ni ìràwọ̀ ati wiwo o, ati kíkà àtẹ́lẹwọ́ àti ife-ìmumi- kódà ki èèyàn kan fẹ mọ̀ nipa rẹ lásán-; torí pé gbogbo ìyẹn wa ninu iṣẹ yẹmiwo ati pípe apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀.
- Ti eyi ba jẹ ẹsan ẹni tí ó lọ ba yẹmiwo, bawo wa ni ẹsan yẹmiwo gan fúnra rẹ ṣe maa ri?
- Ìrun ogójì ọjọ́ yẹn maa tó o, kii ṣe dandan fun un ki o da a pada, ṣùgbọ́n ko nii gba ẹsan rẹ.