- Ṣíṣe leewọ sisọ pe: "Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti iwọ naa ba fẹ", ati nnkan ti o jọ ìyẹn ninu awọn gbolohun, ninu nnkan ti asopọ mọ Ọlọhun ń bẹ nibẹ pẹlu lilo harafi waw; nitori pe o wa ninu dida orogun pọ mọ Ọlọhun nibi awọn gbolohun ati awọn ọrọ.
- Nini ẹtọ sisọ pe: "Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti o ba fẹ", ati nnkan ti o jọ ìyẹn, ninu nnkan ti asopọ mọ Ọlọhun n bẹ nibẹ pẹlu lilo gbolohun thummo; nitori aisi nnkan ti a n sọra fun nibẹ.
- Fifi fifẹ rinlẹ fun Ọlọhun, ati fifi fifẹ rinlẹ fun ẹru, ati pe fifẹ ẹru n tẹle fifẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni.
- Kikọ kuro nibi fifi ẹda ṣe akẹgbẹ nibi fifẹ Ọlọhun, koda ki o jẹ pẹlu gbolohun.
- Ti olusọrọ ba ni adisọkan pe dajudaju fifẹ ẹru da gẹgẹ bii fifẹ Ọlọhun- Ọba ti O gbọnngbọn ti O lágbára- ni ti ṣiṣe deedee rẹ nibi kikari ati titu kalẹ, tabi pe dajudaju ẹru ni fifẹ ti o da duro, òun ni ẹbọ nla, ṣùgbọ́n ti o ba ni adisọkan nnkan ti o yàtọ̀ si ìyẹn; oun ni ẹbọ kekere.