- Fifẹ sisọ gbolohun lẹyin rírọ ojo pé: Wọn rọ ojo fun wa pẹlu ọla Ọlọhun ati ikẹ Rẹ.
- Ẹni ti o ba ṣe afiti rírọ ojo ati nnkan ti o yàtọ̀ si i si ara irawọ ni ti dida ati mimu-nnkan-bẹ, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ ti o tobi, ṣugbọn ti o ba ṣe afiti rẹ lori pe okunfa ni, o ti di alaigbagbọ ni ti aigbagbọ kekere; nitori pe ko ki n ṣe okunfa ti sharia tabi ti imọlara.
- Dajudaju idẹra maa n jẹ okunfa fun aigbagbọ ti wọn ṣe aimore si i, o si maa n jẹ okunfa igbagbọ ti wọn ba dupẹ rẹ.
- Kíkọ sisọ gbolohun: “Wọn rọ ojo fun wa pẹlu irawọ bayii bayii, ko da ki wọn gbero asiko pẹ̀lú rẹ, láti dènà àtẹ̀gùn lọ síbi ẹbọ.
- Jijẹ dandan siso ọkan papọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi fifa awọn idẹra wá, ati titi awọn iya kuro.