- Ọla ti n bẹ fun Abu Bakr Siddiq - ki Ọlọhun yọnu si i- ati pé dajudaju oun ni ẹni tó lọ́lá jùlọ ninu awọn Sahaaba, oun ló sì lẹtọọ ju gbogbo eniyan lọ lati jẹ khalifa lẹyin iku Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).
- Dajudaju kikọ mọṣalaṣi sori awọn saare jẹ́ ọ̀kan ninu awọn aburu ti awọn ìjọ tó ṣaaju ṣe.
- kíkọ̀ fun wa lati mú awọn saare ni àáyè ijọsin ti ao waa maa kirun nibẹ tabi ki a maa kirun si oku ibẹ lara, ati kíkọ̀ fun wa lati kọ́ mọṣalaṣi tabi òrùlé rìbìtì sí ori awọn saare, kí ó lè jẹ́ iṣọra fun wa kuro nibi kíkó sinu ẹbọ latara iyẹn.
- Iwani ní iṣọra kuro nibi àṣejù nipa awọn ẹni rere, nitori pé ó máa ń fani lọ sí inu ẹbọ ni.
- Pípàtàkì ohun tí Anabi n wá wa ní isọra kuro ní idi rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba tí ó tẹnumọ ọn ní ó ku ọjọ márùn-ún ti yio jade laye.