- Ìgbẹ́kẹ̀lé Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, oun ni pe ko si ẹni ti o le mu oore wa afi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu danu afi Ọlọhun.
- Kikọ kuro nibi ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe oun ni nnkan ti wọn maa n fura mọ aburu latara rẹ, ti o si maa n ṣẹri ẹni kúrò nibi iṣẹ.
- Ifuramọ idunnu ko ki n ṣe ara ifi ẹyẹ furamọ daadaa tabi aburu ti a kọ kuro nibẹ, bi ko ṣe pe o wa ninu nini ero daadaa pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Gbogbo nnkan maa n ṣẹlẹ̀ pẹlu kadara Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.