Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún...
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀...

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ka aaya yii: {Òun ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ọ; àwọn āyah aláìnípọ́n-na wà nínú rẹ̀ - àwọn sì ni ìpìlẹ̀ Tírà -, onípọ́n-na sì ni ìyókù. Ní ti àwọn tí ìgbúnrí kúrò níbi òdodo wà nínú ọkàn wọn, wọn yóò máa tẹ̀lé èyí t’ó ní pọ́n-na nínú rẹ̀ láti fi wá wàhálà àti láti fí wá ìtúmọ̀ (òdì) fún un. Kò sì sí ẹni t’ó nímọ̀ ìtúmọ̀ rẹ̀ àfi Allāhu. Àwọn àgbà nínú ìmọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n ń sọ pé: “A gbà á gbọ́. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni gbogbo rẹ̀ (ti sọ̀kalẹ̀).” Kò sí ẹni t’ó ń lo ìrántí àyàfi àwọn onílàákàyè} [Aal Imraan: 7]. O sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ti o ba ti ri awọn ti n tẹle ohun ti o ruju ninu ẹ, àwọn ti Ọlọhun sọ nìyẹn, ki ẹ ṣọ́ra fun wọn”.

Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe: "Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ".

Lati ọdọ An-Nu‘maan ọmọ Basheer - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Apejuwe ẹni ti o duro nibi aala Ọlọhun ati ẹni ti o ko sinu rẹ, da gẹgẹ bi apejuwe awọn ijọ kan ti wọn mu aje lori ọkọ oju-omi, ni apakan wọn wa bọ si oke rẹ ti apakan wọn si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ rẹ ba ti wa fẹ bu omi mu wọn yio gba ọdọ awọn ti wọn wa l'oke wọn kọja, ni wọn wa sọ pe: Ao ba si lu iho kan si ọdọ wa ki a ma fi fi ṣuta kan awọn ti wọn wa ni oke wa, ti wọn ba fi wọn silẹ pẹlu nkan ti wọn gbero gbogbo wọn maa parun, ti wọn ba wa gba wọn ni ọwọ mu (ti wọn kọ fun wọn) wọn o la (iyẹn awọn ti wọn gbero lati lu iho), ati pe gbogbo wọn pata ni yio la».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".

Láti ọ̀dọ̀ Ibnu Mas’ud Al-Ansaariy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ọkùnrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pé: Nǹkan ọ̀gùn mi ti kú, fun mi ni nǹkan ti maa gùn, ni o wa sọ pé: “Mi o ni”, arákùnrin kan wa sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, maa júwe fun un ẹni tí ó maa fun un ni nǹkan ti o maa gùn, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e”.

Lati ọdọ Sahl ọmọ Sa'd- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni ọjọ́ Khaibar pé: Dajudaju maa fun arakunrin kan ni asia yii ni ọla ti Ọlọhun maa ti ipasẹ rẹ fun wa ni iṣẹgun, o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa nífẹ̀ẹ́ rẹ”, o sọ pe: Àwọn ènìyàn sùn ní alẹ́ náà tí wọ́n ń jiroro laarin ara wọn tani wọn yoo fun.” Nígbà ti ilẹ̀ mọ́, àwọn èèyàn lọ ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti ọkọọkan ninu wọn si n fẹ ki wọn fun oun, o sọ pe: “Ibo ni ‘Ali ọmọ Abu Talib wà”? Wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ojú n dùn ún. O sọ pe: “Ẹ ranṣẹ si i”, wọn si mu u wa ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa tutọ́ si oju rẹ mejeeji, o si ṣe adura fun un, o si gbadun gẹgẹ bii pe inira kan kan ko mu u, o wa fun un ni asia náà. Ali wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki n maa ba wọn ja titi wọn fi maa da bii wa? O sọ pe: “Maa lọ ni pẹlẹpẹlẹ titi waa fi dé agbegbe wọn, lẹyin naa pe wọn sinu Isilaamu, sọ nnkan ti o jẹ dandan le wọn lori ninu ẹtọ Ọlọhun fun wọn nibẹ. Mo fi Ọlọhun bura, ki Ọlọhun fi arákùnrin kan ṣoṣo mọna latara rẹ, o loore fun ẹ ju ki o ni ràkúnmí pupa lọ".

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”

Lati ọdọ Tamīm ad-Dāriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ, pẹlu iyi abiyi tabi iyẹpẹrẹ ẹni yẹpẹrẹ, ni iyi kan ti Ọlọhun maa fi fun Isilaamu niyi ati iyẹpẹrẹ kan ti Ọlọhun maa fi yẹpẹrẹ iṣe keferi» Tamīm ad-Dāriy maa n sọ pe: Mo mọ ìyẹn ni ara awọn ara-ile mi, oore ati iyì ti ṣẹlẹ̀ fun ẹni tí o gba Isilaamu nínú wọn, ti iyẹpẹrẹ ati sísan isakọlẹ si ṣẹlẹ fun ẹni ti o jẹ keferi ninu wọn.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina".

Lati ọdọ ọmọ 'Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ni àárọ̀ jiju okuta ipari, ti o si wa lori rakunmi rẹ pé: "Ba mi mu okuta kekere kan" mo wa mu awọn okuta kekere meje fun un, awọn ni okuta kéékèèké tí a maa n fi ìka méjì jù, o wa bẹ̀rẹ̀ si nii ju wọn si atẹlẹwọ rẹ, o si n sọ pe: "Awọn iru awọn wọnyi ni ẹ maa ju" lẹyin naa o sọ pe: "Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin".

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'ud ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pé: "Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.

Lati ọdọ 'Adiyyu ọmọ Haatim, lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu".