- Iro idunnu fun awọn Musulumi pe dajudaju ẹsin wọn maa pada fọnka si gbogbo ipin ilẹ̀.
- Iyi jẹ ti Isilaamu ati awọn Musulumi ti iyẹpẹrẹ si jẹ ti aigbagbọ ati awọn alaigbagbọ.
- Ẹri n bẹ nibẹ ninu awọn ẹri ìjẹ́ anabi ati ami ninu awọn ami rẹ pẹlu pe ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe sọ.