- Ọla ti o n bẹ fun 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-, ati ijẹrii ojiṣẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun un, pẹlu ifẹ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ fun un, ati ifẹ rẹ fun Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ.
- Iṣojukokoro awọn saabe lori daadaa ati iyara wọn lọ síbẹ̀.
- Ṣíṣe ẹkọ nibi ija lofin ati gbigbe aironujinlẹ ju silẹ ati awọn ohun tii ko inira ba eniyan ti ko si bukaata fun un.
- Ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ifunni ni iro rẹ nipa ibori awọn Juu, ati wiwo oju mejeeji 'Ali ọmọ Abu Talib san lati ọwọ rẹ mejeeji pẹlu iyọnda Ọlọhun.
- Nnkan ti a gba lero ti o tobi julọ ninu ijagun soju ọna Ọlọhun ni ki awọn eniyan wọnú Isilaamu.
- Dajudaju ipepe maa n ṣẹlẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ ni, wọn kọ́kọ́ maa ni ki alaigbagbọ o wọnu Isilaamu pẹlu sisọ gbolohun ijẹrii mejeeji, lẹyin naa wọn maa pa a láṣẹ pẹlu awọn ọran-anyan Isilaamu lẹyin ìyẹn.
- Ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ sinu Isilaamu, ati nnkan ti o wa nibẹ ninu oore fun ẹni ti wọn n pe ati olupepe, ẹni ti wọn n pe le mọna ti wọn si maa san olupepe lẹ́san ti o tobi.