- Ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi imọna, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe naa, iru ẹsan ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un, ati pe ìyẹn wa ninu titobi ọla Ọlọhun ati pipe ọrẹ Rẹ.
- Ewu ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi anu, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe náà, iru ẹṣẹ ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un.
- Ẹsan wa ninu iran iṣẹ, ẹni ti o ba pepe lọ sibi dáadáa, iru ẹsan ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un, ẹni ti o ba si pepe lọ sibi aburu, iru ẹṣẹ ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un.
- O jẹ dandan fun Musulumi lati ṣọ́ra ki wọn ma baa wo o kọṣe pẹlu dida ẹṣẹ rẹ ni gbangba, ti awọn eniyan si n ri i, nitori pe yoo maa da ẹṣẹ pẹlu ẹni ti o ba kọṣe rẹ, koda ki o ma ṣe e lojukokoro lori ìyẹn.