- Kikari ìránṣẹ́ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si gbogbo aye, ati pe itẹle rẹ jẹ dandan, ati pipa gbogbo àwọn ofin rẹ pẹlu Sharia rẹ.
- Ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ini adisọkan igbagbọ rẹ pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i ninu awọn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn patapata- ko nii ṣe e ni anfaani.
- Ẹni ti ko ba gbọ nipa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti ipepe Isilaamu ko si de etiigbọ rẹ, oun jẹ ẹni ti o ni àwíjàre, alamọri rẹ ni ọrun si wa lọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
- Ṣíṣe anfaani pẹlu Isilaamu maa wa si ìmúṣẹ koda ki o jẹ pe o ku diẹ ti eeyan maa ku, koda ki o jẹ ninu aarẹ ti o le koko, niwọn igba ti ẹmi ko ba i tii de ọna ọfun.
- Titun ẹsin awọn alaigbagbọ ṣe- ti Juu ati Nasara n bẹ ninu wọn- jẹ aigbagbọ.
- Didarukọ Juu ati Nasara- ninu hadiisi náà- jẹ itaniji fun ẹni ti o yàtọ̀ si wọn; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe iwe n bẹ fun Juu ati Nasara, ti ọrọ wọn ba wa ri báyìí, a jẹ pe ẹni tí o yàtọ̀ si wọn ti iwe ko si fun wọn ni ẹtọ si i ju wọn lọ, ati pe gbogbo wọn, wiwọ inu ẹsin rẹ jẹ dandan fun wọn ati itẹle rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.